Posts

Leyin Kolington ati Oloogbe Barrister emi tun ni asaaju nidi ise fuji......Obesere pariwo s'ita

Image
Agbaakin fun gbogbo Ile Yoruba,  Alaaji Abass Akande Obesere, ti pariwo sita lose to koja pe oun ko ni oga nidi ise fuji rara,Omorapala gege bi awon kan se n pe e ti so pe leyin Oloogbe  Sikiru Ayinde Barrister ati Baba -kebe- n Kwara iyen Alaaji Kollington Ayinla ,pe ki enikeni ma se pe ara re ni oga oun nidi ise Fuji. Ori eto kan lori redio nilu Ibadan ni Omorapala ti soro yii.O tun so pe oun ko setan lati pari ija pelu Wasiu Ayinde rara nitori pe alaaganna okunrin kan ti jise fun oun ri pe laelae ki oun ma se pari ija pelu Wasiu. Sa, o idi ti alaaganna yii se jise to ni i se pelu Olori ebi Arabambi ni ko ye enikeni.

Wasiu Ayinde Pariwo: Emi ko ni mo ni ki awon omoose mi kan egbe FIBAN labuku

Image
Gbajumo osere fuji nni, Alaaji Wasiu Ayinde ti ke gbajare pe oun ko loun ran awon omoose oun lati tabuku egbe awon sorosoro FIBAN ninu iforowero ti won se pelu ileese BBC. Oluaye fuji ni gbogbo ohun ti awon omoose oun so yii oun ko ran won nise nitori pe egbe ti oun feran pupo ti oun si maa n saponle e daadaa legbe awon sorosoro yii. O te siwaju ninu oro e pe lati ojo to pe ni ajosepo gidi ti wa laarin oun atawon oniroyin, oun ko si koyan awon eeyan naa kere rara. Bi e ko ba gbagbe, nibi ayeye ojoobi ogota odun Oba Ilu Itori, Oba Fatai Akorede Akamo ni wahala ti sele laarin gbajumo sorosoro ori radio, Wole Sorunke ti awon eeyan mo si MC Murphy atawon omoota kan ti won wa nibi ayeye yii, sugbon ariwo ti okunrin sorosoro naa pa ni pe awon omoose Wasiu ni won lu oun.  Bakan naa la gbo pe Cappo-Detutti bi awon kan se ma n pe Wasiu Ayinde fun MC Murphy ni egberun lona ogorun-un naira. Ju gbogbo e lo, Mayegun Ile Yoruba ti so pe oun ko kan egbe FIBAN labuku rara.