Leyin Kolington ati Oloogbe Barrister emi tun ni asaaju nidi ise fuji......Obesere pariwo s'ita
Agbaakin fun gbogbo Ile Yoruba, Alaaji Abass Akande Obesere, ti pariwo sita lose to koja pe oun ko ni oga nidi ise fuji rara,Omorapala gege bi awon kan se n pe e ti so pe leyin Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ati Baba -kebe- n Kwara iyen Alaaji Kollington Ayinla ,pe ki enikeni ma se pe ara re ni oga oun nidi ise Fuji.
Ori eto kan lori redio nilu Ibadan ni Omorapala ti soro yii.O tun so pe oun ko setan lati pari ija pelu Wasiu Ayinde rara nitori pe alaaganna okunrin kan ti jise fun oun ri pe laelae ki oun ma se pari ija pelu Wasiu.
Sa, o idi ti alaaganna yii se jise to ni i se pelu Olori ebi Arabambi ni ko ye enikeni.